Numeri 26:58
Numbers 26:58 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu,
Numbers 26:58 in English
Numbers 26:58 · Berean Standard Bible
These were the families of the Levites: The Libnite clan, the Hebronite clan, the Mahlite clan, the Mushite clan, and the Korahite clan. Now Kohath was the father of Amram,
Context
56Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.” 57Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni;
ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati;
ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari. 58Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi;
ìdílé àwọn ọmọ Libni,
ìdílé àwọn ọmọ Hebroni,
ìdílé àwọn ọmọ Mahili,
ìdílé àwọn ọmọ Muṣi,
ìdílé àwọn ọmọ Kora.
(Kohati ni baba Amramu, 59orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. 60Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.