Native Bible

Numbers 26:59 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.

Numbers 26:59 in English

Numbers 26:59 · Berean Standard Bible

and Amram’s wife was named Jochebed. She was also a daughter of Levi, born to Levi in Egypt. To Amram she bore Aaron, Moses, and their sister Miriam.

Context

57Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari. 58Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu, 59orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. 60Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. 61Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.