Numeri 26:56
Numbers 26:56 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”
Numbers 26:56 in English
Numbers 26:56 · Berean Standard Bible
Each inheritance is to be divided by lot among the larger and smaller tribes.”
Context
54Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ. 55Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í. 56Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.” 57Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni;
ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati;
ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari. 58Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi;
ìdílé àwọn ọmọ Libni,
ìdílé àwọn ọmọ Hebroni,
ìdílé àwọn ọmọ Mahili,
ìdílé àwọn ọmọ Muṣi,
ìdílé àwọn ọmọ Kora.
(Kohati ni baba Amramu,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.