Native Bible

Numbers 26:62 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.

Numbers 26:62 in English

Numbers 26:62 · Berean Standard Bible

The registration of the Levites totaled 23,000, every male a month old or more; they were not numbered among the other Israelites, because no inheritance was given to them among the Israelites.

Context

60Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. 61Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.) 62Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn. 63Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko. 64Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.