Native Bible

Numbers 14:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere!

Numbers 14:41 in English

Numbers 14:41 · Berean Standard Bible

But Moses said, “Why are you transgressing the commandment of the LORD? This will not succeed!

Context

39Nígbà tí Mose sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọkún gidigidi. 40Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.” 41Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere! 42Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín. 43Nítorí pé àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń bẹ níwájú yín, ẹ̀yin yóò sì ti ipa idà ṣubú. Nítorí pé, ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.