Native Bible

Numbers 14:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín.

Numbers 14:42 in English

Numbers 14:42 · Berean Standard Bible

Do not go up, lest you be struck down by your enemies, because the LORD is not among you.

Context

40Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.” 41Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere! 42Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín. 43Nítorí pé àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń bẹ níwájú yín, ẹ̀yin yóò sì ti ipa idà ṣubú. Nítorí pé, ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.” 44Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láìjẹ́ pé àpótí ẹ̀rí Olúwa tàbí Mose kúrò nínú ibùdó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.