Numeri 14:39
Numbers 14:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Mose sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọkún gidigidi.
Numbers 14:39 in English
Numbers 14:39 · Berean Standard Bible
And when Moses relayed these words to all the Israelites, the people mourned bitterly.
Context
37Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-ààrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa. 38Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne ló yè é. 39Nígbà tí Mose sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọkún gidigidi. 40Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.” 41Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.