Numeri 10:25
Numbers 10:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.
Numbers 10:25 in English
Numbers 10:25 · Berean Standard Bible
Finally, the divisions of the camp of Dan set out under their standard, serving as the rear guard for all units, with Ahiezer son of Ammishaddai in command.
Context
23Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase. 24Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini. 25Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn. 26Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri, 27Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.