Native Bible

Nahum 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”

Nahum 2:9 in English

Nahum 2:9 · Berean Standard Bible

“Plunder the silver! Plunder the gold!” There is no end to the treasure, an abundance of every precious thing.

Context

7A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà, wọn a sì máa lu àyà wọn. 8Ninefe dàbí adágún omi, tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn. 9“Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!” 10Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. 11Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.