Nahumu 2:10
Nahum 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.
Nahum 2:10 in English
Nahum 2:10 · Berean Standard Bible
She is emptied! Yes, she is desolate and laid waste! Hearts melt, knees knock, bodies tremble, and every face grows pale!
Context
8Ninefe dàbí adágún omi,
tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ.
“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,
ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn. 9“Ẹ kó ìkógun fàdákà!
Ẹ kó ìkógun wúrà!
Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,
àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!” 10Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:
ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn,
ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́
àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. 11Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà
àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,
níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn,
àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù. 12Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀,
ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀,
ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀
àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.