Native Bible

Nahum 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.

Nahum 2:4 in English

Nahum 2:4 · Berean Standard Bible

The chariots dash through the streets; they rush around the plazas, appearing like torches, darting about like lightning.

Context

2Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́. 3Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì. 4Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná. 5Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀. 6A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.