Native Bible

Nahum 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.

Nahum 2:6 in English

Nahum 2:6 · Berean Standard Bible

The river gates are thrown open and the palace collapses.

Context

4Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná. 5Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀. 6A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀. 7A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà, wọn a sì máa lu àyà wọn. 8Ninefe dàbí adágún omi, tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.