Nahumu 2:3
Nahum 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì.
Nahum 2:3 in English
Nahum 2:3 · Berean Standard Bible
The shields of his mighty men are red; the valiant warriors are dressed in scarlet. The fittings of the chariots flash like fire on the day they are prepared, and the spears of cypress have been brandished.*
Context
1Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe.
Pa ilé ìṣọ́ mọ́,
ṣọ́ ọ̀nà náà,
di àmùrè,
ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le múra gírí. 2Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò
gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run,
tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́. 3Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa;
àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó.
Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná
ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán;
igi firi ni a ó sì mì tìtì. 4Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,
wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro.
Wọn sì dàbí ètùfù iná;
tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná. 5Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;
síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;
wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀,
a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.