Native Bible

Nahum 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe. Pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà, di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le múra gírí.

Nahum 2:1 in English

Nahum 2:1 · Berean Standard Bible

One who scatters advances against you, O Nineveh. Guard the fortress! Watch the road! Brace yourselves!* Summon all your strength!

Context

1Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe. Pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà, di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le múra gírí. 2Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́. 3Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.