Nahumu 1:5
Nahum 1:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Nahum 1:5 in English
Nahum 1:5 · Berean Standard Bible
The mountains quake before Him, and the hills melt away; the earth trembles at His presence— the world and all its dwellers.
Context
3Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára;
Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà.
Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì,
ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. 4Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;
Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ.
Baṣani àti Karmeli sì rọ.
Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀. 5Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,
àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́,
ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,
àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 6Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?
Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?
Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;
àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀. 7Rere ni Olúwa,
òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.