Nahumu 1:4
Nahum 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ. Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.
Nahum 1:4 in English
Nahum 1:4 · Berean Standard Bible
He rebukes the sea and dries it up; He makes all the rivers run dry. Bashan and Carmel wither, and the flower of Lebanon wilts.
Context
2Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san,
Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú.
Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. 3Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára;
Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà.
Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì,
ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. 4Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;
Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ.
Baṣani àti Karmeli sì rọ.
Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀. 5Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,
àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́,
ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,
àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 6Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?
Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?
Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;
àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.