Nahumu 1:11
Nahum 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.
Nahum 1:11 in English
Nahum 1:11 · Berean Standard Bible
From you, O Nineveh, comes forth a plotter of evil against the LORD, a counselor of wickedness.
Context
9Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa?
Òun yóò fi òpin sí i,
ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì. 10Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú
wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn
a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ. 11Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá
tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa
ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú. 12Báyìí ni Olúwa wí:
“Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye,
ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀,
nígbà tí òun ó bá kọjá.
Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójúmọ́. 13Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ
èmi yóò já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.