Nahumu 1:9
Nahum 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì.
Nahum 1:9 in English
Nahum 1:9 · Berean Standard Bible
Whatever you plot against the LORD, He will bring to an end. Affliction will not rise up a second time.
Context
7Rere ni Olúwa,
òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, 8ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá
ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin;
òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀. 9Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa?
Òun yóò fi òpin sí i,
ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì. 10Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú
wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn
a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ. 11Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá
tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa
ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.