Native Bible

Nahum 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ.

Nahum 1:10 in English

Nahum 1:10 · Berean Standard Bible

For they will be entangled as with thorns and consumed like the drink of a drunkard— like stubble that is fully dry.

Context

8ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀. 9Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì. 10Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ. 11Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú. 12Báyìí ni Olúwa wí: “Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye, ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọjá. Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójúmọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.