Native Bible

Mark 12:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀.

Mark 12:9 in English

Mark 12:9 · Berean Standard Bible

What then will the owner of the vineyard do? He will come and kill those tenants, and will give the vineyard to others.

Context

7“Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ 8Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà. 9“Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀ òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé. 11Èyí ni iṣẹ́ Olúwa ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.