Marku 12:10
Mark 12:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀ òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
Mark 12:10 in English
Mark 12:10 · Berean Standard Bible
Have you never read this Scripture: ‘The stone the builders rejected has become the cornerstone.
Context
8Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà. 9“Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀
òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé. 11Èyí ni iṣẹ́ Olúwa
ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?” 12Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.