Native Bible

Micah 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

Micah 6:13 in English

Micah 6:13 · Berean Standard Bible

Therefore I am striking you severely, to ruin you because of your sins.

Context

11Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn? 12Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn? 13Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. 14Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrín rẹ. Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà. 15Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ olifi, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ; ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.