Mika 6:11
Micah 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?
Micah 6:11 in English
Micah 6:11 · Berean Standard Bible
Can I excuse dishonest scales or bags of false weights?
Context
9Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà,
láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.
“Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án. 10Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà
ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀,
àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú? 11Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́
pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú,
pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn? 12Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá;
àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké
àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn? 13Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́,
láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.