Mika 6:9
Micah 6:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà, láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ. “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án.
Micah 6:9 in English
Micah 6:9 · Berean Standard Bible
The voice of the LORD calls out to the city (and it is sound wisdom to fear Your name): “Heed the rod and the One who ordained it.
Context
7Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò,
tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró?
Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi,
èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi? 8Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára,
àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?
Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú,
àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀. 9Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà,
láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.
“Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án. 10Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà
ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀,
àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú? 11Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́
pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú,
pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.