Native Bible

Micah 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

Micah 6:8 in English

Micah 6:8 · Berean Standard Bible

He has shown you, O man, what is good. And what does the LORD require of you but to act justly, to love mercy, and to walk humbly with your God?

Context

6Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga? Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan? 7Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò, tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró? Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi? 8Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀. 9Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà, láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ. “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án. 10Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀, àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.