Native Bible

Micah 6:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrín rẹ. Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.

Micah 6:14 in English

Micah 6:14 · Berean Standard Bible

You will eat but not be satisfied, and your hunger will remain with you. What you acquire, you will not preserve; and what you save, I will give to the sword.

Context

12Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn? 13Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. 14Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrín rẹ. Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà. 15Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ olifi, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ; ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì. 16Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà; ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.