Mika 6:15
Micah 6:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ olifi, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ; ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.
Micah 6:15 in English
Micah 6:15 · Berean Standard Bible
You will sow but not reap; you will press olives but not anoint yourselves with oil; you will tread grapes but not drink the wine.
Context
13Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́,
láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. 14Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó;
ìyàn yóò wà láàrín rẹ.
Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu,
nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà. 15Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè
ìwọ yóò tẹ olifi,
ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ;
ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì. 16Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́,
àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu,
tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn,
nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun
àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà;
ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.