Native Bible

Micah 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà;

Micah 3:9 in English

Micah 3:9 · Berean Standard Bible

Now hear this, O leaders of the house of Jacob and rulers of the house of Israel, who despise justice and pervert all that is right,

Context

7Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” 8Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un. 9Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà; 10tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú. 11Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó. Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.