Mika 3:8
Micah 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.
Micah 3:8 in English
Micah 3:8 · Berean Standard Bible
As for me, however, I am filled with power by the Spirit of the LORD, with justice and courage, to declare to Jacob his transgression and to Israel his sin.
Context
6Nítorí náà òru yóò wá sórí yín,
tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan,
òkùnkùn yóò sì kùn fún yín,
tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀.
Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì
ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn. 7Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì
àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú.
Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn,
nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” 8Ṣùgbọ́n ní tèmi,
èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa,
láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un,
àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un. 9Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu,
àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli,
tí ó kórìíra òdodo
tí ó sì yí òtítọ́ padà; 10tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.