Native Bible

Micah 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀. Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.

Micah 3:6 in English

Micah 3:6 · Berean Standard Bible

Therefore night will come over you without visions, and darkness without divination. The sun will set on these prophets, and the daylight will turn black over them.

Context

4Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa, ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe. 5Báyìí ni Olúwa wí, “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i. 6Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀. Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn. 7Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” 8Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.