Native Bible

Matthew 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

Matthew 3:4 in English

Matthew 3:4 · Berean Standard Bible

John wore a garment of camel’s hair, with a leather belt around his waist. His food was locusts and wild honey.

Context

2Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” 3Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” 4Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. 5Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani. 6Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò Jordani.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.