Native Bible

Matthew 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani.

Matthew 3:5 in English

Matthew 3:5 · Berean Standard Bible

People went out to him from Jerusalem and all Judea and the whole region around the Jordan.

Context

3Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” 4Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. 5Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani. 6Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò Jordani. 7Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.