Native Bible

Matthew 3:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Matthew 3:2 in English

Matthew 3:2 · Berean Standard Bible

and saying, “Repent, for the kingdom of heaven is near.”

Context

1Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea. 2Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” 3Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” 4Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.