Matiu 26:36
Matthew 26:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.”
Matthew 26:36 in English
Matthew 26:36 · Berean Standard Bible
At that time Jesus went with His disciples to a place called Gethsemane, and He told them, “Sit here while I go over there and pray.”
Context
34Jesu wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” 35Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí. 36Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. 38Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.