Native Bible

Matthew 26:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”

Matthew 26:38 in English

Matthew 26:38 · Berean Standard Bible

Then He said to them, “My soul is consumed with sorrow to the point of death. Stay here and keep watch with Me.”

Context

36Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. 38Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.” 39Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.” 40Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Peteru, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.