Native Bible

Matthew 26:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.

Matthew 26:35 in English

Matthew 26:35 · Berean Standard Bible

Peter replied, “Even if I have to die with You, I will never deny You.” And all the other disciples said the same thing.

Context

33Peteru sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” 34Jesu wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” 35Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí. 36Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.