Native Bible

Malachi 1:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn.

Malachi 1:7 in English

Malachi 1:7 · Berean Standard Bible

By presenting defiled food on My altar. But you ask, ‘How have we defiled You *?’ By saying that the table of the LORD is contemptible.

Context

5Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni Olúwa, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Israẹli.’ 6“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’ 7“Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn. 8Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.