Native Bible

Malachi 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Malachi 1:9 in English

Malachi 1:9 · Berean Standard Bible

“But ask now for God’s favor. Will He be gracious? Since this has come from your hands, will He show you favor?” asks the LORD of Hosts.

Context

7“Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn. 8Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 10“Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. 11Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.