Malaki 1:8
Malachi 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Malachi 1:8 in English
Malachi 1:8 · Berean Standard Bible
When you offer blind animals for sacrifice, is it not wrong? And when you present the lame and sick ones, is it not wrong? Try offering them to your governor! Would he be pleased with you or show you favor?” asks the LORD of Hosts.
Context
6“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi.
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’ 7“Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi.
“Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’
“Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn. 8Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 10“Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.