Malaki 1:10
Malachi 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín.
Malachi 1:10 in English
Malachi 1:10 · Berean Standard Bible
“Oh, that one of you would shut the temple doors, so that you would no longer kindle useless fires on My altar! I take no pleasure in you,” says the LORD of Hosts, “and I will accept no offering from your hands.
Context
8Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 10“Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. 11Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 12“Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.