Native Bible

Malachi 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn.

Malachi 1:12 in English

Malachi 1:12 · Berean Standard Bible

“But you profane it when you say, ‘The table of the Lord is defiled, and as for its fruit, its food is contemptible.’

Context

10“Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. 11Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 12“Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. 13Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí. 14“Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.