Native Bible

Malachi 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí.

Malachi 1:13 in English

Malachi 1:13 · Berean Standard Bible

You also say: ‘Oh, what a nuisance!’ And you turn up your nose at it,” says the LORD of Hosts. “You bring offerings that are stolen, lame, or sick! Should I accept these from your hands?” asks the LORD.

Context

11Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 12“Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. 13Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí. 14“Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.