Native Bible

Leviticus 24:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.

Leviticus 24:14 in English

Leviticus 24:14 · Berean Standard Bible

“Take the blasphemer * outside the camp, and have all who heard him lay their hands on his head; then have the whole assembly stone him.

Context

12Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn. 13Olúwa sì sọ fún Mose pé, 14“Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa. 15Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.