Native Bible

Leviticus 24:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.

Leviticus 24:16 in English

Leviticus 24:16 · Berean Standard Bible

Whoever blasphemes the name of the LORD must surely be put to death; the whole assembly must surely stone him, whether he is a foreign resident or native; if he blasphemes the Name, he must be put to death.

Context

14“Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa. 15Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á. 17“ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á. 18Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.