Native Bible

Leviticus 24:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.

Leviticus 24:12 in English

Leviticus 24:12 · Berean Standard Bible

They placed him in custody until the will of the LORD should be made clear to them.

Context

10Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan. 11Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.) 12Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn. 13Olúwa sì sọ fún Mose pé, 14“Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.