Native Bible

Leviticus 19:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

Leviticus 19:18 in English

Leviticus 19:18 · Berean Standard Bible

Do not seek revenge or bear a grudge against any of your people, but love your neighbor as yourself.* I am the LORD.

Context

16“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu. Èmi ni Olúwa. 17“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀. 18“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa. 19“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe. 20“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.