Lefitiku 19:17
Leviticus 19:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.
Leviticus 19:17 in English
Leviticus 19:17 · Berean Standard Bible
You must not harbor hatred against your brother in your heart. Directly rebuke your neighbor, so that you will not incur guilt on account of him.
Context
15“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn, ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ. 16“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu. Èmi ni Olúwa. 17“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀. 18“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa. 19“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.