Native Bible

Leviticus 19:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu. Èmi ni Olúwa.

Leviticus 19:16 in English

Leviticus 19:16 · Berean Standard Bible

You must not go about spreading slander among your people. You must not endanger the life * of your neighbor. I am the LORD.

Context

14“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ. Èmi ni Olúwa. 15“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn, ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ. 16“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu. Èmi ni Olúwa. 17“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀. 18“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.