Lefitiku 11:3
Leviticus 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.
Leviticus 11:3 in English
Leviticus 11:3 · Berean Standard Bible
You may eat any animal that has a split hoof completely divided and that chews the cud.
Context
1Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 2“Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ. 3Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ. 4“ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.