Native Bible

Leviticus 11:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.

Leviticus 11:4 in English

Leviticus 11:4 · Berean Standard Bible

But of those that only chew the cud or only have a divided hoof, you are not to eat the following:* The camel, though it chews the cud, does not have a divided hoof; it is unclean for you.

Context

2“Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ. 3Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ. 4“ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín. 6Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátákò ẹsẹ̀; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.